Àlàyé Bitkoini bí ọmọ ọdún márùń

Láti ọwọ́ Nik Custodio 2013/12/12open in new window

Tí ohun tí Bitkoini jẹ́ kò bá tí yé ẹ…

Ka wò wípé, a jọ jóko sí ibi ìgbafẹ́.

Mo mún èso ápù kan dání. Mo wá fún ẹ ní èso náà.

Níbáyìí ìwọ ti ní èso ápù kan, èmi sì ní òdo.

Ṣèbí, óyé ẹ?

Jẹ́ kí a farabalẹ́ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀:

A ò nílò ẹnì kẹta láti mu fún ara wa.

A ò nílò láti pe Uncle Tommy (tí ó jẹ́ olókìkí adájọ́) láti jóko tí wa kí ó lè ri dájú pé èso ápù náà wá láti ọwọ́ mi sí tì ẹ.

Tì é ni èso ápù náà! Mi ò lè fún ẹ ni èso ápù míràn mọ́ torí mi ò ni ìmíì mọ́. Kò sí ní ìkáyọ́ mi mọ́. Èso ápù náà ti kúrò lọ́wọ́ mi pátápátá. Níbáyìí o ti ní gbogbo àṣẹ lórí èso ápù náà. Tí o bá fẹ́ o lè fún ọ̀rẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ni ọ̀rẹ́ rẹ lè fún ọ̀rẹ́ ti rẹ náà pèlú. Àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ.

Nítorí bẹ̀ bi pàṣípàrọ̀ ojú kojú ṣe rí nì yẹn. Mo rò ó wípé bá kan náà lórí, bóyá ògẹ̀dẹ̀ ni mò ń fún ẹ ni, ìwé ni, bóyá ìdá mẹ́rin tàbí odindin owó dollar kan…

Ṣùgbọ́n ó dà bi wípé mo tín kánjú.

Ká padà sí orí ọ̀rò èso ápù!

Níbáyìí ká ní pé, mo ní èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà. Mo ma fún ẹ ní èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà ti tèmi.

Ẹn o! Ibi awí ladé yìí.

Dàárò fún ìṣéjú kan ná. Báwo ni o ṣe ma mọ̀ pé èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà ti ó fi ìgbà kan jẹ́ tèmi, ti wá di tì ẹ àti pé ṣé tì ẹ nìkan ni?

Ó ti ń dojúrú, àbí? Báwo ni o ṣe ma mọ̀ wípé mí ò tí kọ́kọ́ so èso ápù náà mọ́ àtẹ̀jíṣẹ́ lórí ayélujára sí Uncle Tommy? Tàbí sí Joe, ọ̀rẹ́ mìi tàbí sí Lisa ọ̀rẹ́ mìi náà?

Bóyá mo sì ní àwọn àdàkọ sí orí ẹ̀rọ kòmpútà tèmi. Bóyá mo fi sí orí ayélujára tí àwọn ènìyàn mílíọ́nù ti gbàá sílẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí o ti ri, pàṣípàrọ̀ ti orí ẹ̀rọ kòmpútà ó jẹ́ ìṣòro dí ẹ̀. Fí èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà ránṣẹ́ kò dàbí ká fi èso ápù gangan ránṣẹ́.

Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti kòmpútà kan tilẹ̀ ní orúkọ fún ìṣòro yìí. Òun ni wán pè ní ìṣòro ìnáwó onílọ́po méjì. Ṣùgbọ́n kò tó ìyọnu. Ǹkan tí mo fẹ́ ko mọ̀ ni wípé, ó ti tó ìgbà dí ẹ̀ tí ó ti ń rúwọn lójú. Síbẹ̀ wọn ò tí ri yanjú.

Títí di báyìí.

Sùgbọ́n ẹ jẹ́ ka gbìyànjú fún rara wa láti wá ọ̀nà àbáyọ.

Ìwé àkọsílẹ̀ t'ìnáwó

Bóyá a ní láti ṣe àbójútó àwọn èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà nínú ìwé àkọsílẹ̀ t’ìnáwó kan. Èyí jẹ́ ìwé tí a fi má n mójútó gbogbo ìdúnàdúrà wa - Ìwé ìsirọ́ owó.

Ìwé àkọsílẹ̀ t'ìnáwó yìí, ní láti wà ní àyè ara ẹ̀, kí ó sì wà ní ìkápá ẹnìkan, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ ti orí ẹ̀rọ kòmpútà ni.

Kání, bi Blizzard, ilé iṣẹ́ tí wọ́n ṣẹ̀dá eré ìdárayá ti orí ayélujára tí a mọ̀ sí World of Warcraft, ni gbogbo àwọn idà inọ́ wan tí ó ṣọ̀wán tí wón ti ṣe láti láíláí nínú “ìwé àkọsílẹ̀ ti orí ẹ̀rọ kòmpútà” ti won. Ó da bẹ́ẹ̀! Báyìí a ti yanjú ẹ̀, Irú ènìyàn bí ti wọn èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà wa.

Àwọn ìṣòro

Bótilẹ̀jẹ́pé ìṣòro dí ẹ̀ wà:

  1. Tí èyàn kan láti ilé iṣẹ́ Blizzard wá lọ ṣe àwọn òmíràn si? Ó kọ̀ lè fi kún èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà ti ẹ̀ tó ní sílẹ̀ nígbàkigbà tí ó bà wùú!

  2. Kò dà bí ìgbà tí a jọ jókòó ní ọjọ́ kìníí ànọ́. Nígbà yẹn, èmi àti ìwọ nìkan ni. Lílọ nípasẹ̀ Blizzard dà bi pé a lọ mú Uncle Tommy (ẹnì kẹta) kúro ní ilé ẹjọ́ (ṣé mo sọ fún ẹ pé olókìkí ni) láti wá dásí gbogbo ìdúnàádúrà tí a bá ṣe lójúkojú. Báwo ni mo ṣe lè fún ẹ ní èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà bí, ṣo mọ̀ - ìgbà tí à ń fún ra wa ní ojúkojú?

ǹjẹ́ ọ̀nà tilẹ̀ wà tó fẹ́ farapẹ́ ìdúnàádúrà ìjóòkó tèmi n'tìrẹ lórí ẹ̀rọ kòmpútà bí? Ìyẹn fẹ́ le dí ẹ̀…

Ònà Àbáyọ Náà

Ká wá ní ati pín ìwé àkọsílẹ̀ t’ìnáwó yìí- fún gbogbo ènìyàn? Kàkà kí ìwé àkọsílẹ̀ t’ìnáwó náà wà ní orí kòmpútà Blizzard nìkan, ó ma wà ni orí kòmpútà gbogbo ènìyàn. Gbogbo ìdúnàádúrà èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà tí ó ti ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ wá ni ó ma wà ní kíkọ sílẹ̀ nínú ẹ̀.

Kò ṣé yàn jẹ. Mi ò lè fi èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà tí mi ò ní ránṣẹ́ sí ẹ, nítorí ètò náà kò ní ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú ti gbogbo àwọn ènìyàn tókù. Á le láti ṣèrú pèlú ẹ̀. Á jẹ́ ètò tó le láti lé bá. Pàápàá tí ó ba tóbi gan.

Pẹ̀lú kò kín ṣe èyàn kan ló n ṣe àkóso ẹ̀, nítorí bẹ̀, mo mọ̀ pé kò sí ẹni kẹ́ni tí ò kàn lè pinnu láti fún ra ẹ̀ ní èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà si. Àti ìbẹ̀rẹ̀ ni wọ́n ti sọ òfin ètò náà sílẹ̀. Àti pé ìlànà àti òfin ẹ̀ wà ní àrọ́wọ́tó gbogbo àwọn akọètò.

Ó wà níbẹ̀ fún àwọn olóye láti fi ti wọn kun, ṣètọ́jú ẹ̀, dá ààbò òó, mu dára si, àti láti bójúto. Ìwọ náà lè kópa nínú ètò yí, kí o mú ìwé àkọsílẹ̀ t’ìnáwó dé ojúìwọ́n àti kí gbogbo ẹ̀ má a ṣe dede, o lè rí èso áruńdílọ́gbọ̀n ti orí ẹ̀rọ kòmpútà bí èrè. Ní pàtó, nínú ètò náà ọ̀nà kan ṣoṣo tí ó wa làti ṣe àwọn èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà míràn sílẹ̀ nìyẹn.

Mo mu rọrùn dí ẹ̀

… ṣùgbọ́n ètò tí mo ṣàlàyé yìí wà. Òhun ni à ń pè ní ìlànà Bitkoini. Bẹ́èni àwọn èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà ni “bitcoin” tó wà nínú ètò náà

Nítoríbẹ̀, ṣé o rí nkan tí ó ṣẹlẹ̀? Kíni Ìwé àkọsílẹ̀ t’ìnáwó ti gbangban gbà láàyé?

  1. Ṣé o rántí pé ìlanà ètò ẹ̀ wà ní àrọ́wọ́tọ́ gbogbo ènìyàn? Gbogbo oye èso ápù náà lápapọ̀ tí ó wà nínú ìwé àkọsílẹ̀ t’ìnáwó gbangba ni wọ́n ti sọ láti ìbẹ̀rẹ̀. Mo mọ iye gangan tí ó wà. Mo mọ̀ wípé oye tó wà nínú ètò náà kò pọ̀.

  2. Tí mo bá ṣe pàsípàrọ̀ mo ti mọ̀ báyìí wípé èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà tí ó kúrò ní ìkáwọ́ mi ti di tì ẹ pátápátá. Tẹ́lẹ̀ mi ò kín lè sọ nípa àwọn ǹkan bẹ́ẹ̀. Ìwé àkọsílẹ̀ t’ìnáwó gbangba ni ó ma mu dójúìwọ̀n àti láti rí dájú.

  3. Nítorí pé ó jẹ́ ìwé àkọsílẹ̀ t’ìnáwó gbangba, mi ò nílo Uncle Tommy láti rí pé mi ò ṣe èrú tàbí tẹ díẹ̀ si fúnramí tàbí fi ránṣé lẹ́mẹ̀jì tàbí lẹ́mẹta…

    Nínú ètò náà, pàṣípàrọ̀ èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà ti wà dàbí ti ojúkojú. Àfi bí wípé mo mú èso ápù gangan láti ọwọ́ mi si inú àpò ẹ. Àti bí ti ìgbà tí ajọ jókó sí ibi ìgbafẹ́, pàṣípàrọ̀ náà wáyé ní àrín ènìyàn méjì péré. Ìwọ àti èmi- a ò nílò Uncle Tommy níbẹ̀ láti báwa fi òntẹ̀ tẹ̀ ẹ́.

Ní ọ̀rọ̀ kan, ó dàbí ǹkan tí a lè fi ojú rí.

Ṣùgbọ́n, ṣé ẹ mọ ǹkan tí ó dára níbẹ̀? Ti orí ẹ̀rọ kòmpútà náà ṣì ni. A lè ma wá ma sòwò pẹ̀lu ẹgbẹ̀rún èso ápù tàbí ní mílíọ́nù kan ápù, tàbí pàápàá ní ápù tí ó kéré sí ẹyọ̀kan. Mo lè fi ránṣẹ́ ní ìṣẹ́jú àáyá, mo tún le fi sínú àpò orí ẹ̀rọ kòmpútà ẹ, bóyá mo wà ní orílẹ̀-èdè Nicaragua tí ìwọ dẹ̀ wà ní ìlú New York.

Mo ti ẹ tún lè jẹ́ kí àwọn ǹkan ti orí ẹ̀rọ kòmpútà ìmíì gbáralé àwọn èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà wònyí! Ti orí ẹ̀rọ kòmpútà kúkú ni. Bóyá mo lè so ọ̀rọ̀ tí mo kọ mọ tàbí bóyá kí n so àwọn ǹkan pàtàkì òmíràn mọ; bí ìwé àdéhun, tàbí ìwé-ẹ̀rí ìṣura, tabi ìwé ìdánimọ̀.

Nítorínà èyí dára púpọ̀! Báwo ni a ṣe maṣe mọ ọwọ́ tí a fi mú tàbi mọ iye tí a ma gbélé àwọn “èso ápù ti orí ẹ̀rọ kòmpútà” yìí? Wọ́n wúlò púpọ̀, àbí bẹ́ẹ̀kọ́?

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ló ń jiyàn lórí ẹ̀ bàyìí. Àríyànjiyà náà ń lọ l’àárín oríṣiríṣi àwọn onímọ̀ ti ọrọ̀ ajé. L’àárín àwọn olóṣèlú. L’àárín àwọn akọètò ẹ̀rọ kòmpútà. O nílò láti tẹ́tí sí wọn. Àwọn kan ní ọgbọ́n. Wọ́n ti ṣi àwọn kan lọ́nà. Àwọn kan sọ wípé ètò náà gbé oye lórí gan, bẹ́ẹ̀ni àwọn sọ wípé kò já mọ́ ǹkankan. Ẹnìkan ti ẹ̀ fi oye kan pàtó si: ó ní èso ápù kan jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùń dọ́là. Àwọn kan sọ wípé wúrà orí ẹ̀rọ kòmpútà ni, àwọn kan ní owó ni. Àwọn kan náà tún ní ó dàbí òdòdó. Àwọn kan ní ó ma yí ayé yìí padà. Àwon kan náà ní kò lè pẹ́, á tó kúrò nílẹ̀.

Mo ní èrò tèmi nípa ẹ̀.

Ìyẹn dẹ̀ di ọ́jọ míràn. Sùgbọ́n ní báyìí, o ti mọ̀ nípa Bitkoini ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Recommend Reading (Updated 2017)

“You Don’t Understand Bitcoin Because You Think Money is Real”open in new window by Maria Bustillosopen in new window is a good follow-up read.

You can also read more about Ethereum and Smart Contracts hereopen in new window. Enjoy!

Awọn onitumọ
Oladele Falese

Olufowosi
BitMEX