Bítkọìnì Dà Bi Eré-ìdárayá

látọwọ @thebitcoinrabbi 2021/01/13open in new window

Mo ún sábà ṣe àlàyé bí #bitkoini ṣe ún ṣiṣẹ́ àti bó ṣe jẹ́ aláìkòsójúkan nípa lílo àpẹrẹ ìdíje eré-ìdárayá. Mo ti ríi pé èyí únṣe ìrànlọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè tó wọ́ pọ̀:

Ìbéèrè: Ta ni ó dá eré bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá sílẹ̀?
Ìdáhùn: Ìbéèrè yìí kò ṣe pàtàkì. Ẹnikẹ́ni tó bá wù lóle kópa nínú eré yìí. Ká sọ pé ẹni tó dá eré náa sílẹ̀ fẹ́ yí òfin erè tàbí pé ó fẹ́ fún ara rẹ̀ ní ẹ̀bún eré tàbí ohun mírán. Kó sí èyí tó kàn wá nípá ohun tó bá rò lórí eré wa.

Ìbéèrè: Ta ni ó ún sàkóso eré náà?
Ìdáhùn: Ẹnìkankan kò ṣe àkóso, gbogbo wa lé pinu láti kópa nínú eré náà. Gbogbo wa la mọ̀ òfin rẹ̀, tí a sì tẹ̀ le. Bẹ́ ẹ̀ sì ni tí ẹnì kan bá fẹ́ ṣe òjóró, a ó lé wọn kúrò nínú erè náà. Tí ẹnì kan bá fún ara rẹ̀ ní ẹ̀bùn eré tí kò bá ìlànà mú, a kò ní kọ bi ara sí wọn.

Ìbéèrè: Bá wo ni a ṣe mọ pé àwọn òfin eré kò ní yípadà?
Ìdáhùn: Gbogbo wa lati gbà láti tẹlé wọn nígbà tí a bẹrẹ eré. Ẹnikẹni tó bá fẹ kópa pẹlú àwọn òfin eré náà lé tẹsíwájú pẹlú eré náà. Tí ẹnikẹni bá fẹ ṣe àyípadà àwọn òfin yìí, yí ò lọ dá eré tì ẹ sílẹ ni.

Ìbéèrè: Ṣé ó ṣe é jà ní jìbìtì?
Ìdáhùn: Gbogbo ohun tó ún ṣẹlẹ lojú le rí. Ojú wa rí gbogbo orí pápá ìdíje àti ẹbùn eré. Tí ẹni kan bá ún ṣe òjóró, a le bá wọn wí.

Ìbéèrè: Kí lódé tó ṣe níye lórí?
Ìdáhùn: Nítorí pé a ti pinu láti kópa nínú ìdíje eré náà, o níye síwa. Ẹnikẹni tó bá fẹ kópa gbọdọ gbà láti tẹlé iye àti ẹbùn eré wa.

Ó níye nítorípé mo díye le. Ọwọ wa ló kù sí.

Ìbéèrè: Wọn mọ le fòfin dè é?
Ìdáhùn: Ó ṣe é ṣe. Ṣe bí a kàn fẹsẹ gbá bọọlù ni. A à ba ùnkankan jẹ ẹ. Ìjọba le pinu láti dí enìyàn lọnà láti ṣe eré yìí sùgbọn wọn kò le dínà àgbékalẹ rẹ, elòmíràn níbòmíràn yíò tẹsíwájú pẹlú eré náà.

Ìbéèrè: Ṣé kí un kópa níbẹ?
Ìdáhùn: Ẹ ṣe ohun tóbá wù yín. Mò ún gbádùn ará mí pẹlú bọọlù-àfẹsẹgbá, ẹ le kópa níbẹ tàbí ẹ le gbádùn ara yín nínú òsi.

Awọn onitumọ
Cryptico

Olufowosi
BitMEX