MO ÙN HODL

látọwọ GameKyuubi 2013/12/18open in new window

Mo kọ akọlé ùn ní ẹmẹjì nítorípé mo mọ pé mi ò kọ dáadáa láákọkọ. Aṣìṣe náà tún ni. Kò rí kó ṣe rí.

Ọmọge mi wà ní ilé otí, iye owó Bitkoini ti jábọ. KÍ NI ÌDÍ Ẹ TÍ MO ṢE ÚN HODL? MÀ Á SỌ FÚN YÍN.

Oníìnádúrà burúkú ni mí, mo sì MỌ PÉ ONÍÌNÁDÚRÀ BURÚKÚ NI MÍ. Bẹẹni ẹyin onníìnádúrà gidi tí ẹ mọ ìgbà tó lewó at’ìgbà tó dínwó ràá gbàá tàá tí ẹ mọ owó pa, ó dáà bẹẹ.

Bẹẹ náà sì ni àwọn tọwọ wọn kò yá ún sọ pé MÓ GBÉ Ó TÍ ÚN DÍNWÓ MO GBỌDỌ TÀÁ he he he, tí wọn bá ti táá wọn ó tún sọ pé OLÚWA O KÍLÓDÉ TÍ MO FI TÀÁ nígbà tí àwọn onníìnádúrà ỌLỌPỌLỌ tí WỌN MỌ OHUN TÍ WỌN ÙNṢE ràá lọwọ wọn, sùgbọn mọ fẹ kí ẹ mọ ùnkankan? Ẹmi ò sí ní àrin wọn. Nígbàtí àwọn onníìAYÉ nádúrà bá ràá padà èmi ti wà nínú ọjà, KÍ Ẹ MỌ TA NI Ẹ ÚN TÚ JẸ ÀWỌN onníìnádúrà ẸMI KỌ~!

Àwọn ẹjọ yẹyẹ pé “Ò BÁ MỌ KÍ O TI TÀÁ” ÙN BÁ MỌ KỌ. ÙN BÁ MỌ KÍ UNTI TÀÁ. ÙN BÁ MỌ KÍ UNTI TÀÁ KÓ TÓ DI PÉ WỌN TÀÁ, ÀTI KÍ UNTI TÀÁ KÓ TÓ DI PÉ WỌN RÀÁ ṢUGBỌN KÌ Í ṢE GBOGBO AYÉ LÓ GBỌN BÍ I YÍN.

Nígbà ọjà ọwọn nìkan ni ẹ ti le tàá tó bá se pé onníìnádúrà dáadáa lẹ jẹ tàbí aláàlá. Àwọn tó kú gbọdọ dìímú.

Nínú gbágàgìdì ọjà bí èyí, àwọn onníìnádúrà le gba owó lọwọ yín tí ẹ bá tàá nìkan.

Awọn onitumọ
Cryptico

Olufowosi
BitMEX