A gbé ẹ̀ yà Bitkoini àkọ́ kọ́ (v.01) jáde

Láti ọwọ́ Satoshi Nakamoto 2009/01/09open in new window

À ń kéde àkọ́ kọ́ jáde Bitkoini, ètò owó ẹ̀ rọ orí kọ̀ mpútà titun, ètò owó ẹ̀ rọ orí kọ̀ mpútà titun, tí ó n lo ìtàkù orí-ò-orí láti dí nínọ́ owó lẹ́ẹ̀mejì. Ó jẹ́ èyí tí ó ní alákòóso púpọ̀, tí ò ní olùpín tàbí aláṣẹ àtòkèwá

Lọ sí bitcoin.org fún àwọn àwòrán.

Ìtọ́kasí ẹ̀dà rẹ̀ rè é: http://downloads.sourceforge.net/bitcoin/bitcoin-0.1.0.rar

Ní orí Windows nìkan fún báyì. Ìlànà ètò to wà ní àrọ́ wọ́ tọ́ gbogbo ènìyàn, ìlanà ètò to wà ní àrọ́ wọ́ tọ́ gbogbo ènìyàn C++

  • Tú fáìlì náà palẹ̀ sínú fáìlì àkópọ̀
  • Tẹ BITCOIN.EXE
  • Fún ara ẹ̀ ló ma lọ sí àwọn ìkoríta tó kù

Tí o bá lè jẹ́ kí ìkoríta kan ma ṣiṣẹ tí ó n gba ìsopọ̀ láyè, Ò ń ṣe ìrànlọ́ wọ́ púpọ̀ fún ìtàkù náà, Ojú- ìsopọ 8333 ní orí olùmójútó ààbò ẹ nílò láti wà ní ṣíṣílẹ̀ kí ó lè gba ìsopọ wọlé.

Ìlànà ètò yí ṣì wà ní ìpele ìbẹ̀rẹ̀ àti ìgbéyẹ̀wò. Kò sí ìdánilójú pé ipò tí ètò yí wà kò ní nílò kí a tun bẹ̀rẹ̀ ní ìgbà kan tí ó bá pọn dandan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ṣe gbogbo ǹkan láti fi àyè sílẹ̀ fún ìdàgbàsókè ọjọ́ iwájú àti ṣíṣe ẹ̀ya ẹ̀.

O lè rí ẹyọ owó nípasè kí èyàn kan fi ránṣẹ́ sí ẹ, tàbí kí o tan Àṣàyàn->Tẹ Ẹyọ Owó láti lọ sí ìkoríta àti ki o tẹ búlọ́kù. Mo mú ìṣòro ẹ̀rí-iṣẹ́ rọnrù gidi gan, nítoríbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ kọ̀mpútà ẹni ma lè tẹ ẹyọ owó ní wákàtí díẹ̀. Ó ma le díẹ̀ si nígbà tí ìdíje bá fún rara ẹ̀ sún ìpele ìṣòro sókè. Ẹyọ owó tí a tẹ̀ gbọ́dọ̀ dúró búlọ́kù ọgọ́fà láti gbó kí á tó lè na.

Ọ̀ nà méjì ló wá láti fi owó ránṣẹ́. Tí olùgbà bá wà lórí ìlà, o lè tẹ́ àdírẹ́sì ìlànà ayélujára wọn, ó ṣì ma lọ, wá kọ́ kọ́ rọ́ gbangba titun kí o ṣì fi ìdúnàdúra ẹ ránṣẹ́ pèlú àyè fún àsọyé. Tí olùgbà kò bá sí ní orí ìlà, ó ṣeé ṣe láti fi ránṣé sí àdírẹ́ sì Bitkoini wọn, èyí tí ó jẹ́ olùyípadà ti kọ́ kọ́ rọ́ gbangba wọn tí wọ́n fún ẹ. Wọ́n á gba ìdúnàdúra wọn nígbà míràn tí wọ́n bá bọ́sí orí ìlà wọ́n á rí búlọ́kù tí ówà.Ọ̀nàyíníìyọnutíẹ̀ tíabáfiàlàyétíòníàsọyéránṣé,asọdíẹ̀ nùnínúìpamọ́ àṣírítíabálo àdírẹ́sì náà ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ṣùgbọ́n ó wúlò bí ọ̀nà míràn tí a tún lè lò tí àwọn olùmúlò méjèjì ò bá sí ní orí ìlà ní ìgbà kan náà tàbí tí olùgbà kò bá lè gba ìsopọ̀ wọlé.

Gbogbo ìṣọ̀ yíká lápapọ̀ jẹ́ ẹyọ owó mílíọ́ nù mọ́ kànlélógún. A ma pin fún ìkoríta ìtàkùn tí wọ́ n bá ti ṣe búlọ́kù, ó ma ma ṣe ìdajì oye tí ó jẹ́ ní gbogbo ọdún mẹ́rin.

ọdún mẹ́rin àkọ́kọ́: mílíọ́nù mẹ́wàá àti ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta ẹyọ owó
ọdún mẹ́ rin tó tèle: mílíọ́ nù márùń àti igba ó lé ládọ́ ta ẹyọ owó
ọdún mẹ́rin tó tèle: mílíọ́nù méjì àti ẹgbẹ̀ta ẹgbẹ̀rún lé ní árùńdínlógún ẹyọ owó
ọdún mẹ́rin tó tèle: mílíọ́nù kan àti ọ̀kẹ́ mẹ́ta lé ní ẹgbàá méjìlá ẹyọ owó
àti bẹ́ẹ̀bẹ́è lọ...

Tí ìyẹn bá ti tán, ètò yí lè gba owó ìdúnàdúra tí ó bá nílò. Ó dá lórí ìdíje ojú ojà, ó ṣeṣe ká rí ìkoríta tí ó lè bá wọn ṣètò ìdúnàdúra ní ọ̀ fẹ́ .

Satoshi Nakamoto


The Cryptography Mailing List Unsubscribe by sending "unsubscribe cryptography" to majord...@metzdowd.com

Awọn onitumọ
Oladele Falese

Olufowosi
BitMEX