Báwo ni a ṣe ma jẹ́ kí àwọn èèyàn Bílíọ̀nù 7.753 mọ̀ nípa ' lightning Network' (Nẹ́tíwọ́kì onírọ́rùn tó yára bíi mọ̀nàmọ́ná)?

Nípasẹ̀ John Cantrell 2022/01/05open in new window

Mo wo iye wa, jẹ́ ká wo bí a ṣelè jẹ́ kí gbogbo ará ayé mọ̀ nípa 'Lightning Network', iye ìgbà tí o lè gbà, àti ǹkan tí a lè ṣe láti jẹ́ kí ìlànà náà yá

láti ní ìmọ̀ nípa 'Lightning Network', ó nílò láti fi btc ránṣẹ sí ìdúnàdúrà ìgbéowósílẹ̀ ti ìbuwọ́lù púpọ̀ oní 2-of-2 pẹ̀lú alábaṣepọ̀ ojú ọ̀nà e. Láti lo ànfàní àyè nínú ìdúnàdúrà yìí, a nílò àgbéwọlé segwit àbínibí kan (1) àti ìṣàgbéjáde ojú ọ̀nà ìgbówósílẹ̀ kan (1). Èyí á pèsè tx tí á fẹ́ẹ̀ tó 121vbytes.

Tí 100% àwọn ìdúnàdúrà nínú blọ́ọ́kì náà bá jẹ́ àwọn ojú ọ̀nà txs, a lè ṣí ojú àwọn bíi 8,264 sí 'Lightning' sí blọ́ọ́kì kan. Pẹ̀lú iye ènìyàn àgbáyé ti Bílíọ̀nù 7.753, ó ma gbà tó àwọn blọ́ọ́kì 938,166 tàbí iye ọdún 17.8 fún gbogbo ènìyàn lórí ayé láti ní ojú ọ̀nà

ṣé a lè ṣe dáadáa si? adúpẹ́ a ní àwọn àṣàyàn méjì. Àṣàyàn kan tí ó ṣe ńṣe ni láti lo 'Batching'. Batching túmọ̀ sí pé a lè ṣí ju ọ̀nà kan nínú ìdúnàdúrà kan. Èyí túmọ̀ sí pé ìṣàgbéjáde òmíràn nínú ìgbówósílẹ̀ tx lé ṣe aṣojú ọ̀nà àfikún kànkan

Àfikún ìṣàgbéjáde kànkan tí a fikun lò bíi 32vbytes. Pẹ̀lú Batching, ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó dára jù ní kí á kún blọ́ọ́kì náà pẹ̀lú ìdúnàdúrà kan (1) pẹ̀lú àgbàwọlé kan (1) àti iye ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣàgbéjáde tí ó lè bamu. Ní 32vbytes sí ìṣàgbéjáde kan, èyí túmọ̀ sí pé a lè ṣí àwọn ojú ọ̀nà 31,247 sí blọ́ọ́kì kan!

Batching fún wa ní ìlọsíwájú 3.78x, ó sì fa ìgbà láti ṣàlàyé fún gbogbo ayé sílẹ̀ di ìgbà ọdún 4.7. Èyí ò banilẹ́rù ṣùgbọ́n ó gbà wípé a lè lo 100% ti àyè blọ́ọ́kì náà fún ìgbà ọdún tó fẹ́ẹ tó ọdún márùn (5). Ní tòótọ́, o ma ṣẹlẹ̀ díẹ̀díẹ̀ fún iye ìgbà tó máa pẹ́. ṣé a lè ṣe dáadáa si?

Ó yí jáde sí pé a lè ṣe é, bóti lẹ̀ jẹ́ wí pé kòlè (rọrùn) jẹ́ èní. Àṣedárasi tó kàn ni láti ṣe àtìlẹ́yìn èèyàn tó ju méjì lọ sí ojú ònà kan àti láti lo àpapọ̀ ìbuwọ́lù láti jẹ́ kí ìwọ̀n ìṣàgbéjáde náà kéré. Ojú ọ̀nà ẹlẹ́gbẹ́ ọ̀pọ̀ jẹ́ kí ìbuwọ́lù ọ̀pọ̀ 2-of-2 gbòòrò si sí N-of-N ìbuwọ́lù ọ̀pọ̀ tó tóbi si

Nínú tíọ́rì, "N" yìí lè jẹ́ 10, 100, ótúlè jẹ́ 1000. Ní àwọn èèyàn 10 sí ojú ònà kan, a lè fi yé àwọn èèyàn 312,470 sí blọ́ọ́kì kan àti gbogbo ayé ní ìgbà ọjọ́ 172. Nígbàtí Batching fún wa ní ìlọsíwájú oní wọ̀nba nínú ṣíṣe, ojú ọ̀nà ẹlẹ́gbẹ́ ọ̀pọ̀ gbà wá lá yè láti ṣe ìwọ̀n ní ìpele bí wọn ṣe tóbi sí.

Ní ti oní tíọ́rì, wọn lè kọ́ wọn ní èní, láìsí ìyàtọ̀ kankan sí Bítkọìnì sùgbọ́n á nílò akitiyan iṣẹ́ àwọn ẹlẹ́rọ tí ó pọ̀, nítorí àwọn ìdíjú ìṣètò ìjìyà 'Lightning'. Sẹ́tútmẹ́tì aláfarawé txs ti 'Eltoo' ṣe ìrọ̀rùn púpọ̀ fún ṣíṣe ti àwọn ojú ọ̀nà ẹlẹ́gbẹ́ ọ̀pọ̀.

Ṣé a lè jẹ́kí àwọn èèyàn gbogbo àgbáyé mọ̀ nípa 'Lightning' ní iye ìgbà tó tọ́?. ó dàbí pé ìdáhùn yẹn jẹ́ bẹ́ẹ̀ni. Níkẹyìn a máa dé bẹ̀. Ǹjẹ́ gbogbo ènìyàn lórí ayé fẹ́ wà lórí 'Lightning' àti nílò ojú ọ̀nà wọn bí? kò dájú ṣùgbọ́n mo ní ìrètí pé á rí bẹ́ẹ̀!

Awọn onitumọ
Learn Yoruba Easily

Olufowosi
Galoy Money